
This is an except of the exceptional translation of Kehinde Folorunsho’s work on Chimamanda Adichie’s “We should all be Feminists”. The work, earlier titled Bibenugan Fun Eto Obirin-a translation of Chimamanda Adichie’s “We should all be Feminists.” was longlisted for the Atelewo Prize for Yoruba Literature in 2025. Folorunsho, an advocate of the development and ppreservation of indigenous languages is also involved in extensive culture projects that preserve identity, culture and sustainability.
Kehinde Folorunsho is a writer, editor, journalist, translator and teacher. He is also the winner of the 2025 Ken Saro Wiwa Prize for Book Review in 2025 (Organised by the Lagos Book and Arts Festival)
Èyí ni àtúnyẹ̀wò alábọ́dé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí mo ṣe ní oṣù kejìlá ọdún ẹgbàáọdún-ó-lé-méjìlá ni TEDxEuston, àpérò ọlọ́dọọdún kan lórí àwọn ìṣòro tí ilẹ̀ adúláwọ̀ ń kojú. Àwọn alágbàsọ láti ọ̀kanòjọ̀kan èto-iṣẹ́ afọ̀wọ̀mọni ló ṣe àwọn oríṣi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe ìpèníjà àti ìmóríyá fún àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ ilẹ̀ adúláwọ̀. Ní bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, mo ti sọ̀rọ̀ níbi àpérò TED mìíràn rí, tí mo ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àkórí ‘Ìjàm̀bà Ìtàn Aláwẹ́ Kan Péré’ lórí bí fífi àìṣedééde sọni lórúkọ ṣe ń mú gbèǹdéke bá èèrò wa, pàápàá jùlọ, ilẹ̀ adúláwọ̀. Ní tèmi, ó dàbí pé fífi àìṣedééde sọni lórúkọ tí mú gbèǹdéke bá bíbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin, àti òye ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin tìkara rẹ̀. Nígbà tí 3 arákùnrin mi Chuks àti ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, tí wọ́n dìjọ ṣagbátẹrù àpérò TEDxEuston kọ̀ jálẹ̀ pé ọ̀rọ̀ọyàn ni fún mi láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ñ ò lè fìtìjú kọhùn sí wọn lẹnu. Mo pinnu láti dọ́rọ̀ sílẹ̀ lórí ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin nítorí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń gbé mi lọ́kàn gidigidi. Mo fura pé ó lè má jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ tí ó lápẹẹrẹ, ṣùgbọ́n mo wòye pé ñ ó fọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ lọ́nà tọ́ ní ìbámu pẹ̀lú èèrò gbogboogbò. Wàyí, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, mo dúró sórí ìtàgé, o dàbí pé mo wà láàrin mọ̀lẹ́bí kan – irúfẹ́ olùgbọ́ tí ó tẹ́tí sí mi pẹ̀lú ìkáàánú, ṣùgbọ́n tí o lè kọtí ikún sí kókó orí ọ̀rọ̀ mi. Ní òpin ohun gbogbo, ìwúrí ńlá ni àtẹ́wọ́ tòun ìnàró wọn jẹ́ fún mi.
Ìbẹnugan Fún Ẹ̀tọ́ Obìnrin
Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ìgbà èwe mi tí ó ṣọ̀wọ́n jùlọ ni Okoloma. Aládùúgbò mi ní; bí ẹ̀gbọ́nkùnrin, ó ríi dájú pé èèrà kan ò rìn mí: bí ọmọkùnrin kan bá ń dá mi lọ́rùn, mà á fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ wẹ́lọ̀ létí Okoloma. Okoloma jẹ́ aláwàdà, ó sì gbọ́n’gbọ́n inú, ó sì máa ń wọ bàtà onímú gogoro bíi ti òyìnbó tí ń da màlúù. Ó wu ni kí á jẹran pẹ́ lẹ́nu, ọ̀nà ọ̀fun ni ò jẹ́, ni ṣàǹgbá fi fọ́ ní oṣù kejìlá ọdún 2005, nígbà tí ó bá ìjàm̀bá ọkọ̀ òfurufú kan lọ lápá gúúsù ilẹ Nàìjíríà. Títí di òní, ñ ò tilẹ̀ lè ṣàkàwé ọgbẹ́ tí ikú rẹ dá sími lọ́kàn. Okoloma jẹ́ ẹni tí mo lè bá jiyàn, bá dápàárá, tí ñ ò sì lè fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún. Òun sì ni ẹ̀dá alààyè àkọ́kọ́ tó kó pè mí ní abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin.
Ṣèbí ọmọ tó ma jẹ àṣàmú, kékeré lá ti ṣẹnu ṣámúṣámú. Ñ o tíí ju ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lọ ní àkókò náà. Ilé rẹ̀ ni a wà, tí a ń ja ara wa níyàn pẹ̀lú kórímágbófo ìmọ̀ tí a rí gbámú nínú àwọn ìwé tí a ti kà lọ́lọ́kanòjọ̀kan. Ñ ò rántí okùnfà ìjìyàn wa lọ́jọ́ tí a ń sọ yìí. Ṣùgbọ́n mo rántí pé bí mo ti ń fi èrí àròfọ̀ mi múlẹ̀, Okoloma wò mí fín ó sì sọ ọ kedere pẹ: ‘Abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin ni ẹ́.’
Kìí ṣe ẹ̀pọ́n rárá. Ṣèbí wọ́n ní pẹ̀lẹ́ lákọ ó lábo – ó dàbí kí wọ́n fi ẹ̀sùn kanni pé, ‘irú yín gan-an ni igi wọ́rọ́kọ́ tí ń daná àlàáfíà ìlú rú.’
Ñ ò tilẹ̀ mọ ìtumọ àpèjá yìí nígbà náà: abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin. Ñ ò sì fẹ́ kí Okoloma mọ̀ pé ọ̀gbẹ̀rì ni mí. Fún ìdí èyí, mo fi ṣosùn mo fi para. Mo sì pinnu pé ohun àkọ́kọ́ tí màá ṣe bí m̄ bá délé ni kí ñ wò ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwédọpọ́n-ọ̀rọ̀.
Ṣèbí ọmọ tó ma jẹ àṣàmú, kékeré lá ti ṣẹnu ṣámúṣámú. Ñ o tíí ju ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lọ ní àkókò náà. Ilé rẹ̀ ni a wà, tí a ń ja ara wa níyàn pẹ̀lú kórímágbófo ìmọ̀ tí a rí gbámú nínú àwọn ìwé tí a ti kà lọ́lọ́kanòjọ̀kan.
****

Ẹ jẹ́ kí ñ yí owó ago síwájú lẹ́yìn ọdún díẹ̀.
Ní ọdún 2003, mo kọ ìtàn àròsọ tí mo pè àkórí ẹ̀ ní Purple Hibiscus, nípa ọkùnrin kan tí ń lù ìyàwó ẹ̀ nílù bààrà, tí iná sì padà dilẹ̀ lẹ́yìn asunṣu jẹ òun tìkara rẹ̀. Nígbà tí mo ń gbé iwé náà lárugẹ ní Nàìjíría, oníwèéròyìn kan, ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé sì ni pẹ̀lú, ní òun fẹ́ gbà mí níyànjú (ẹ sì mọ̀ pé àwọn ọmọ Nàìjíría kìí pẹ́ di alágbọ̀rọ̀dù ọ̀sán gangan.)
Ó ní awuyewuye tí ń lọ lọ́tùn-ún-lósì pé ìwé ìtàn àròsọ mi jẹ́ abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin; àmọ̀ràn re sími – bẹ́ẹ̀ ló ń mirí bí ẹni báni kẹ́dùn bí ó ti ń sọ̀rọ̀ – ni pé kí ñ dẹ̀kun àti máa perami ní abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin, níwọ̀n ìgbà tó ṣe pé àwọn ni irúfẹ́ obìnrin tí ìbànújẹ́ ogun àìrọ́kọ fẹ́ dorí àgbà wọn kodò.
Mo bá pinnu pé irú kán-ún tèmi á ṣọ̀wọ́n láàrín òkúta: tayọ̀tayọ̀ ni màá fi máa fẹ̀họ́nú hàn lórí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.
Kò pẹ́, kò jìnnà, olùkọ́ ilé-ìwé ẹ̀kọ́ gíga kan, obìnrin, ọmọ Nàìjíría, so fún mi pé ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin kìí ṣe àṣà ilẹ̀ adúláwọ̀, àti pé
ẹ̀kọ́ òdì tí mo rí kọ́ nínú àwọn ìwé òyìnbó tí mo ti kà ló fé mú mi sọ àpò ìyà kọ́. (Èyí pamílẹ́rìn-ín púpọ̀, nítorí pé kò sí ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin nínú púpọ̀ ìwé tí mo kó bẹ̀rẹ̀ síí kà: àsọdùn kọ́, màá ti kà gbogbo ìwé ìfẹ́dìtàn tí ilé-iṣẹ́ Mill & Boon tẹ̀ jáde kí ñ tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Ní gboogbo ìgbà tí mo bá sì gbìyànjú àti kà ‘àwọn ìwé ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin alápẹẹrẹ’, bíi súsú bíi rírẹ̀, típá tìkúùkù ni mo fi ń kà wọ́n já.)
Èyí tí à ń wí yìí ń pẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin kìí ṣe àṣà ilẹ̀ adúláwọ̀, mo pinnu pé èmi a máa jẹ́ Onínúdídùn Alábẹnugan Fún Ẹ̀tọ́ Obìnrin Adúláwọ̀. Ọ̀rò yìí àbí mìí’, ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n kan tún ta mi lólogbó pé pípe ara mi ní abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin túmọ sí pé mo rí okùnrin bíi òun tí à bá pa ká fejò sílẹ̀. Nítorí náà, mo tún fi súná mìíràn kọ́rí pé èmi a máa jẹ́ Onínúdídùn Alábẹnugan Fún Ẹ̀tọ́ Obìnrin Adúláwọ̀ Tí Kò Kórira Ọkùnrin, Tí Sì Ń Tọ́tè, Tí Sì Ń Wọ̀ Bàtà Ko-ko-kà Fún Ara Rẹ̀ Láì Bá Ọkùnrin Kán Forí Gbárí.
I’m
Tani kò ṣàì mọ̀ pé kókó èyí ni láti mẹ́nu ayé kúrò, ṣùgbọ́n ohun tó hàn gbañgba-gbàǹgbà ni bí ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin ṣe dì ẹrù àìmọ̀kanmọ̀kàn, sí ọ̀pọ̀ ènìyàn: olúwa rẹ̀ kórìíra ọkùnrin, olúwa rẹ̀ ń yan kọ́mú lódì, olúwa rẹ̀ ò tilẹ̀ fẹ́ gbọ́ àṣà adúláwọ̀ sétí, olúwa rẹ̀ fàáké kọ́rí pé obìnrin ló gbọ́dọ̀ máa ṣàkóso, olúwa rẹ̀ ò fẹ́ ojúlógeéṣe, olúwa rẹ̀ ò fẹ́ máa tuko ibi kọ́lọ́fín ará, ìbínú sáá ni ní gbogbo ìgbà bi aláfiṣe, wọn kìí lò lọ́fíńdà.
Èyí tí à ń wí yìí ń pẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ìbẹnugan fún ẹ̀tọ́ obìnrin kìí ṣe àṣà ilẹ̀ adúláwọ̀, mo pinnu pé èmi a máa jẹ́ Onínúdídùn Alábẹnugan Fún Ẹ̀tọ́ Obìnrin Adúláwọ̀. Ọ̀rò yìí àbí mìí’, ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n kan tún ta mi lólogbó pé pípe ara mi ní abẹnugan fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin túmọ sí pé mo rí okùnrin bíi òun tí à bá pa ká fejò sílẹ̀.
****

Wàyíò, ìṣípayá kan rèé nínú ìrírí ìgbà èwe mi kan.
Nígbà tí mo wà ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Nsukka, ìtẹ̀dó ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní gúúsù-ìlàòrùn Nàìjíría, tíṣà mi sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ sáà tuntun pé ọmọ tí ó bá peregedé jùlọ nínú ìdánwò ráñpẹ́ tí òun yóò fún wa ni yóò joyè alámójútó kíláàsì. Láyé ‘jọ́un, bí igbákejì olùkọ́ ni ipò yìí.
Ojoojúmọ́ ní olúwa rẹ̀ yóò fi ma korúkọ àwọn tó bá ń tojọ́ wẹ́wẹ́, fún sẹ̀ríà tó yẹ, bákan náà ni olúwa yóò fi tọ̀yàyà mú ẹgba tíṣà dání tẹ̀lée nínú kíláàsì. Lóòótọ́, kìíṣe fún ọmọ náà láti já àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́rẹ́. Ṣùgbọ́n ipò tí ó wuyì nìyí fún ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ó wú mi lori jọjan. Mo sì jáwé olúborí nínú ìdánwò ráñpẹ́ náà.
Àmọ́, kàyééfì ló jẹ́ fún mi nígbà tí tíṣà sọpé alámójútó kíláàsì gbọ́dọ̀ jé ọkùnrin. Ó gbàgbé láti sọ èyí ṣáájú; kò yé kí ó ṣàjèjì sí ẹnikẹ́ni pé ọkùnrin làdá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin ni ó ṣepò kejì, a kò ní dé fìlà sórúnkún ẹsẹ̀.
Ohun tí ó kan mí lóminú jùlọ ni pé jẹ́jẹ́layé ni ọmọkùnrin tí a ń sọ yìí, tí kò
nífẹ̀ẹ́ sí máa mú ẹgba kiri láì ṣe ọlọ́jẹ̀. Bẹ́ẹ̀, làádà lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fún èmi.
Ṣùgbọ́n obìnrin ni. Wọ́n sì ní ohun tó yẹni ló yẹni, okùn orùn ò yẹ adìyẹ, báyìí ni ñ ò ṣe lẹ́tọ̀ọ́ sí ipò alámójútó kíláàsì.
Mánigbàgbé ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ fún mi.
Ohun tí a bá tẹra mọ ní ṣíṣe, bó pé bó yá, kò ní jẹ́ tuntun mọ́. Báka náà, bí a bá ń ri nǹkan lójú kan náà, láìpẹ́, kò ní ṣàjèjì mọ́. Tí a bá ń fi ipò alámójútó kíláàsì sọrí ọmọkùnrin, á di báyìí la ń ṣe nílẹ̀ wa. Bí ó bá jẹ́ pé ọkùnrin nìkan ni ó le wà nípò ọ̀gá ilé-iṣẹ́, á di àṣà tí oyún inú pàápàá mọ̀ sí.
Àmọ́, kàyééfì ló jẹ́ fún mi nígbà tí tíṣà sọpé alámójútó kíláàsì gbọ́dọ̀ jé ọkùnrin. Ó gbàgbé láti sọ èyí ṣáájú; kò yé kí ó ṣàjèjì sí ẹnikẹ́ni pé ọkùnrin làdá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin ni ó ṣepò kejì, a kò ní dé fìlà sórúnkún ẹsẹ̀.
****
Èmi máa ń rò pé oun tí ó bójú mu fún mi tọ̀nà fún ẹnikejì mi pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, Louis, ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, onílàákáyè ẹ̀dá. Bí a bá ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, a wí pé, ‘Èmi ò rò pé ayé lé koko fún obìnrin àti pé nǹkan yàtọ̀ bí o ti sọ o. Boya láyé àtijọ́ ṣá, tòní kọ́. Yùngbàyùngbà ni wọ́n wà lóde òní.’ Háà, ibòjú tó bá Louis fíra kọjá òye mi!
Wọ́n ní ilé làbọ̀ sinmi oko. Mo fẹ́ràn ìsinmi ní Nàìjíría, pàápàá jùlọ, ní ìlú Èkó, ibùdó káràkátà tí ó tóbi jùlọ lórílẹ́ èdè náà. Nígbà mìíràn, lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, tí ooru bá ti kásẹ̀ ńlẹ̀ ti ìlú náà tẹlẹ̀ múyẹ́, èmi àti ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí máa ń gbé mìlíkì jáde lo sọ́dọ̀ sèékódùn. Ní irú ìrọ̀lẹ́ bẹ́ẹ̀, èmi àti Louis bá fàájì lọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́.
Èmi máa ń rò pé oun tí ó bójú mu fún mi tọ̀nà fún ẹnikejì mi pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, Louis, ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, onílàákáyè ẹ̀dá. Bí a bá ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, a wí pé, ‘Èmi ò rò pé ayé lé koko fún obìnrin àti pé nǹkan yàtọ̀ bí o ti sọ o. Boya láyé àtijọ́ ṣá, tòní kọ́. Yùngbàyùngbà ni wọ́n wà lóde òní.’ Háà, ibòjú tó bá Louis fíra kọjá òye mi!

Leave a comment